Lagos State Ministry of Justice

Committed to bringing justice to your doorstep

IKEDE PATAKI

Ijọba ipinle Eko n rọ araalu paapaa gbogbo olugbe Magodo Residential Scheme lati fọkanbalẹ lori iṣẹlẹ to waye laipẹ yii ti Oloye Adebayọ Adeyiga atawọn ẹgbẹ Shangisha Landlords Association fi ẹtan ko awọn ọlọpaa lọ si Magodo lati fi tipa fidi idajọ ile-ẹjọ mulẹ.

Ijọba ṣakiyesi pe awọn ọlọpaa ti wọn waa fidi idajọ naa mulẹ kii ṣe awọn ọlọpaa kootu rara; nitori awọn ọlọpaa kootu ko mọ nnkan nipa igbesẹ ti wọn gbe lọjọ naa ni Magodo. Igbesẹ yii tun lodi si igbekalẹ ile-ẹjọ ilẹ wa.

Ijọba ipinle Eko fẹẹ fi da awọn araalu loju pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati fi awọn to lọwọ si ọrọ naa jofin, bẹẹ nijọba ko ni yẹsẹ lati maa bọwọ fun ofin la i ṣegbe lẹyin ẹnikankan.

Bakan naa nijọba n lo anfaani yii lati kilọ fun awọn eeyan wọnyi pe ki wọn pa gbogbo akọle ti wọn ti kọ sara ile awọn olugbe Magodo rẹ kiakia, bẹẹ ni ki awọn araalu fi ṣe oju lalakan fi n ṣọri. Bi wọn ba si ri ẹnikẹni to ba tun fẹẹ dan iru iwa to lodi sofin bẹẹ wo, ki wọn fi to ijoba leti kia.

Olukede

Moyọsọrẹ Onigbanjo, SAN

Agbẹjọro agba fun ijọba ati kọmiṣanna fun eto idajọ nipinlẹ Eko

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdun 2021

IKEDE PATAKI
Scroll to top